O si ṣe li ọjọ Ahasi ọmọ Jotamu ọmọ Ussiah, ọba Juda, ti Resini, ọba Siria, ati Peka ọmọ Remaliah, ọba Israeli, gokè lọ si Jerusalemu lati jà a li ogun, ṣugbọn nwọn kò le bori rẹ̀.