Isa 13:3-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Emi ti paṣẹ fun awọn temi ti a yà si mimọ́, emi ti pe awọn alagbara mi pẹlu fun ibinu mi, ani awọn ti nwọn yọ̀ ninu ọlanla mi.

4. Ariwo ọ̀pọlọpọ lori oke, gẹgẹ bi ti enia pupọ̀: ariwo rudurudu ti ijọba awọn orilẹ-ède, ti a kojọ pọ̀: Oluwa awọn ọmọ-ogun gbá ogun awọn ọmọ-ogun jọ.

5. Nwọn ti ilẹ okerè wá, lati ipẹkun ọrun, ani, Oluwa, ati ohun-elò ibinu rẹ̀, lati pa gbogbo ilẹ run.

6. Ẹ hu; nitori ọjọ Oluwa kù si dẹdẹ; yio de bi iparun lati ọdọ Olodumare wá.

7. Nitorina gbogbo ọwọ́ yio rọ, ọkàn olukuluku enia yio si di yiyọ́.

8. Nwọn o si bẹ̀ru: irora ati ikãnu yio dì wọn mu; nwọn o wà ni irora bi obinrin ti nrọbi: ẹnu yio yà ẹnikan si ẹnikeji rẹ̀; oju wọn yio dabi ọwọ́-iná.

Isa 13