1. Ọ̀RỌ-ìmọ niti Babiloni ti Isaiah ọmọ Amosi ri.
2. Ẹ gbe ọpágun soke lori oke giga, ẹ kọ si wọn, ẹ juwọ, ki nwọn ba le lọ sinu ẹnu-odi awọn ọlọla.
3. Emi ti paṣẹ fun awọn temi ti a yà si mimọ́, emi ti pe awọn alagbara mi pẹlu fun ibinu mi, ani awọn ti nwọn yọ̀ ninu ọlanla mi.
4. Ariwo ọ̀pọlọpọ lori oke, gẹgẹ bi ti enia pupọ̀: ariwo rudurudu ti ijọba awọn orilẹ-ède, ti a kojọ pọ̀: Oluwa awọn ọmọ-ogun gbá ogun awọn ọmọ-ogun jọ.
5. Nwọn ti ilẹ okerè wá, lati ipẹkun ọrun, ani, Oluwa, ati ohun-elò ibinu rẹ̀, lati pa gbogbo ilẹ run.
6. Ẹ hu; nitori ọjọ Oluwa kù si dẹdẹ; yio de bi iparun lati ọdọ Olodumare wá.
7. Nitorina gbogbo ọwọ́ yio rọ, ọkàn olukuluku enia yio si di yiyọ́.