2. Kro 29:9-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Sa wò o, awọn baba wa ti ti ipa idà ṣubu, ati awọn ọmọkunrin wa, ati awọn ọmọbinrin wa, ati awọn obinrin wa wà ni igbekun nitori eyi.

10. Njẹ o wà li ọkàn mi lati ba Oluwa Ọlọrun Israeli dá majẹmu, ki ibinu rẹ̀ kikan ki o le yipada kuro lọdọ wa.

11. Ẹnyin ọmọ mi, ẹ máṣe jafara nisisiyi: nitori ti Oluwa ti yàn nyin lati duro niwaju rẹ̀, lati sìn i, ati ki ẹnyin ki o mã ṣe iranṣẹ fun u, ki ẹ si mã sun turari.

12. Nigbana li awọn ọmọ Lefi dide, Mahati, ọmọ Amasai, ati Joeli, ọmọ Asariah, ninu awọn ọmọ Kohati: ati ninu awọn ọmọ Merari, Kiṣi, ọmọ Abdi, ati Asariah, ọmọ Jehaleeli: ati ninu awọn ọmọ Gerṣoni, Joah, ọmọ Simma, ati Edeni, ọmọ Joah:

13. Ati ninu awọn ọmọ Elisafani, Ṣimri ati Jegieli: ati ninu awọn ọmọ Asafu, Sekariah ati Mattaniah.

14. Ati ninu awọn ọmọ Hemani, Jehieli ati Ṣimei: ati ninu awọn ọmọ Jedutuni, Ṣemaiah ati Ussieli.

15. Nwọn si kó awọn arakunrin wọn jọ, nwọn si yà ara wọn si mimọ́, nwọn si wá nipa aṣẹ ọba gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, lati gbá ile Oluwa mọ́.

16. Awọn alufa si wọ inu ile Oluwa lọhun lọ, lati gbá a mọ́, nwọn si mu gbogbo ẽri ti nwọn ri ninu tempili Oluwa jade si inu agbala ile Oluwa. Awọn ọmọ Lefi si kó o, nwọn si rù u jade gbangba lọ si odò Kidroni.

2. Kro 29