HESEKIAH si ranṣẹ si gbogbo Israeli ati Juda, o si kọ iwe pẹlu si Efraimu ati Manasse, ki nwọn ki o wá sinu ile Oluwa ni Jerusalemu, lati pa ajọ irekọja mọ́ si Oluwa, Ọlọrun Israeli.