Nigbana li awọn ọmọ Lefi dide, Mahati, ọmọ Amasai, ati Joeli, ọmọ Asariah, ninu awọn ọmọ Kohati: ati ninu awọn ọmọ Merari, Kiṣi, ọmọ Abdi, ati Asariah, ọmọ Jehaleeli: ati ninu awọn ọmọ Gerṣoni, Joah, ọmọ Simma, ati Edeni, ọmọ Joah: