20. Nigbana ni Hesekiah, ọba, dide ni kutukutu; o si kó awọn olori ilu jọ, o si gòke lọ sinu ile Oluwa.
21. Nwọn si mu akọ-malu meje wá, ati àgbo meje, ati ọdọ-agutan meje, ati obukọ meje fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ fun ijọba na, ati fun ibi mimọ́ na, ati fun Juda. O si paṣẹ fun awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni, lati fi wọn rubọ lori pẹpẹ Oluwa.
22. Bẹ̃ni awọn alufa pa awọn akọ-malu na, nwọn si gba ẹ̀jẹ na, nwọn si fi wọ́n ara pẹpẹ: bẹ̃ gẹgẹ nigbati nwọn pa awọn àgbo, nwọn fi ẹ̀jẹ na wọ́n ara pẹpẹ; nwọn pa awọn ọdọ-agutan pẹlu nwọn si fi ẹ̀jẹ na wọ́n ara pẹpẹ.
23. Nwọn si mu awọn òbukọ ẹbọ-ẹ̀ṣẹ wá siwaju ọba ati ijọ enia na: nwọn si fi ọwọ wọn le wọn lori.
24. Awọn alufa si pa wọn, nwọn si fi ẹ̀jẹ wọn ṣe ilaja lori pẹpẹ, lati ṣe etutu fun gbogbo Israeli; nitoriti ọba paṣẹ, ki a ṣe ẹbọ sisun ati ẹbọ-ẹ̀ṣẹ fun gbogbo Israeli.
25. O si mu awọn ọmọ Lefi duro ninu ile Oluwa, pẹlu kimbali, pẹlu ohun-elo orin, ati pẹlu duru, gẹgẹ bi aṣẹ Dafidi, ati ti Gadi, ariran ọba, ati Natani, woli, nitori aṣẹ Oluwa ni lati ọwọ awọn woli rẹ̀.