Bẹ̃ni awọn alufa pa awọn akọ-malu na, nwọn si gba ẹ̀jẹ na, nwọn si fi wọ́n ara pẹpẹ: bẹ̃ gẹgẹ nigbati nwọn pa awọn àgbo, nwọn fi ẹ̀jẹ na wọ́n ara pẹpẹ; nwọn pa awọn ọdọ-agutan pẹlu nwọn si fi ẹ̀jẹ na wọ́n ara pẹpẹ.