Nwọn si mu akọ-malu meje wá, ati àgbo meje, ati ọdọ-agutan meje, ati obukọ meje fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ fun ijọba na, ati fun ibi mimọ́ na, ati fun Juda. O si paṣẹ fun awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni, lati fi wọn rubọ lori pẹpẹ Oluwa.