2. A. Ọba 15:17-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Li ọdun kọkandilogoji Asariah ọba Juda ni Menahemu ọmọ Gadi bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli, o si jọba ọdun mẹwa ni Samaria.

18. O si ṣe eyi ti o buru li oju Oluwa: on kò si lọ kuro ninu ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ọmọ Nebati ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀, li ọjọ rẹ̀ gbogbo.

19. Fulu ọba Assiria si gbé ogun tì ilẹ na: Menahemu si fi ẹgbẹrin talenti fadakà fun Fulu, ki ọwọ rẹ̀ ki o le pẹlu on lati fi idi ijọba na mulẹ lọwọ rẹ̀.

20. Menahemu si fi agbara gbà owo na lọwọ Israeli, ani lọwọ gbogbo awọn ọlọrọ̀, ãdọta ṣekeli fadakà lọwọ olukuluku enia, lati fi fun ọba Assiria. Bẹ̃ni ọba Assiria yipada, kò si duro ni ilẹ na.

21. Ati iyokù iṣe Menahemu, ati gbogbo eyiti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli?

22. Menahemu si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀; Pekahiah ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

23. Ni ãdọta ọdun Asariah ọba Juda, Pekahiah ọmọ Menahemu bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli ni Samaria, o si jọba ọdun meji.

24. O si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa: on kò si lọ kuro ninu ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀.

25. Ṣugbọn Peka ọmọ Remaliah, olori-ogun rẹ̀, dì rikiṣi si i, o si kọlù u ni Samaria, li odi ile ọba, pẹlu Argobu, ati Arie, ati ãdọta enia ninu awọn ọmọ Gileadi pẹlu rẹ̀: o si pa a, o si jọba ni ipò rẹ̀.

26. Ati iyokù iṣe Pekahiah, ati gbogbo eyiti o ṣe, kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli.

27. Li ọdun kejilelãdọta Asariah ọba Juda ni Peka ọmọ Remaliah bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli ni Samaria, o si jọba li ogun ọdun.

28. O si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa: on kò lọ kuro ninu ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀.

29. Li ọjọ Peka ọba Israeli ni Tiglat-pileseri ọba Assiria de, o si kó Ijoni, ati Abel-betmaaka, ati Janoa, ati Kedeṣi, ati Hasori, ati Gileadi, ati Galili, gbogbo ilẹ Naftali, o si kó wọn ni igbèkun lọ si Assiria.

30. Hoṣea ọmọ Ela si dì rikiṣi si Peka ọmọ Remaliah, o si kọlù u, o si pa a, o si jọba ni ipò rẹ̀, li ogun ọdun Jotamu ọmọ Ussiah.

31. Ati iyokù iṣe Peka, ati gbogbo eyiti o ṣe, kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli.

2. A. Ọba 15