Fulu ọba Assiria si gbé ogun tì ilẹ na: Menahemu si fi ẹgbẹrin talenti fadakà fun Fulu, ki ọwọ rẹ̀ ki o le pẹlu on lati fi idi ijọba na mulẹ lọwọ rẹ̀.