37. Eyi ni Mose na ti o wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Woli kan li Oluwa Ọlọrun nyin yio gbé dide fun nyin ninu awọn arakunrin nyin, bi emi; on ni ki ẹ gbọ́ tirẹ.
38. Eyi na li ẹniti o wà ninu ijọ ni ijù pẹlu angẹli na ti o ba a sọ̀rọ li òke Sinai, ati pẹlu awọn baba wa: ẹniti o gbà ọ̀rọ ìye lati fifun wa:
39. Ẹniti awọn baba wa kò fẹ gbọ́ tirẹ, ṣugbọn nwọn tì i kuro lọdọ wọn, nwọn si yipada li ọkàn wọn si Egipti;
40. Nwọn wi fun Aaroni pe, Dà oriṣa fun wa ti yio ma tọ̀na ṣaju wa: nitori bi o ṣe ti Mose yi ti o mu wa ti ilẹ Egipti jade wá, a kò mọ̀ ohun ti o ṣe e.
41. Nwọn si yá ere ẹgbọ̀rọ malu ni ijọ wọnni, nwọn si rubọ si ere na, nwọn si nyọ̀ ninu iṣẹ ọwọ́ ara wọn.
42. Ọlọrun si pada, o fi wọn silẹ lati mã sìn ogun ọrun; bi a ti kọ ọ ninu iwe awọn woli pe, Ẹnyin ara ile Israeli, ẹnyin ha mu ẹran ti a pa ati ẹbọ fun mi wá bi li ogoji ọdun ni iju?
43. Ẹnyin si tẹwọgbà agọ́ Moloku, ati irawọ oriṣa Remfani, aworan ti ẹnyin ṣe lati mã bọ wọn: emi ó si kó nyin lọ rekọja Babiloni.
44. Awọn baba wa ni agọ ẹri ni ijù, bi ẹniti o ba Mose sọrọ ti paṣẹ pe, ki o ṣe e gẹgẹ bi apẹrẹ ti o ti ri;
45. Ti awọn baba wa ti o tẹle wọn si mu ba Joṣua wá si ilẹ-ini awọn Keferi, ti Ọlọrun lé jade kuro niwaju awọn baba wa, titi di ọjọ Dafidi;
46. Ẹniti o ri ojurere niwaju Ọlọrun, ti o si tọrọ lati ri ibugbe fun Ọlọrun Jakọbu.