1. O si ṣe, nigbati awa kuro lọdọ wọn, ti a sì ṣikọ̀, awa ba ọ̀na tàra wá si Kosi, ni ijọ keji a si lọ si Rodu, ati lati ibẹ̀ lọ si Patara:
2. Nigbati awa si ri ọkọ̀ kan ti nrekọja lọ si Fenike, awa wọ̀ ọkọ̀, a si ṣí.
3. Nigbati awa si ti ri Kipru li òkere, ti awa fi i si ọwọ́ òsi, awa gbé ori ọkọ̀ le Siria, a si gúnlẹ ni Tire: nitori nibẹ̀ li ọkọ̀ yio gbé kó ẹrù silẹ.
4. Nigbati a si ri awọn ọmọ-ẹhin, awa duro nibẹ̀ ni ijọ meje: awọn ẹniti o tipa Ẹmí wi fun Paulu pe, ki o máṣe lọ si Jerusalemu.
5. Nigbati a si ti lò ọjọ wọnni tan, awa jade, a si mu ọ̀na wa pọ̀n; gbogbo nwọn si sìn wa, pẹlu awọn obinrin ati awọn ọmọde titi awa fi jade si ẹhin ilu: nigbati awa si gunlẹ li ebute, awa si gbadura.
6. Nigbati a si ti dágbere fun ara wa, awa bọ́ si ọkọ̀; ṣugbọn awọn si pada lọ si ile wọn.
7. Nigbati a si ti pari àjo wa lati Tire, awa de Ptolemai; nigbati a si kí awọn ará, awa si ba wọn gbé ni ijọ kan.
8. Ni ijọ keji awa lọ kuro, a si wá si Kesarea: nigbati awa si wọ̀ ile Filippi Efangelisti, ọkan ninu awọn meje nì; awa si wọ̀ sọdọ rẹ̀.
9. Ọkunrin yi si li ọmọbinrin mẹrin, wundia, ti ima sọtẹlẹ.
10. Bi a si ti wà nibẹ̀ li ọjọ pipọ, woli kan ti Judea sọkalẹ wá, ti a npè ni Agabu.