O si ṣe, nigbati awa kuro lọdọ wọn, ti a sì ṣikọ̀, awa ba ọ̀na tàra wá si Kosi, ni ijọ keji a si lọ si Rodu, ati lati ibẹ̀ lọ si Patara: