Iṣe Apo 19:34-41 Yorùbá Bibeli (YCE)

34. Ṣugbọn nigbati nwọn mọ̀ pe Ju ni, gbogbo wọn li ohùn kan, niwọn wakati meji ọjọ, kigbe pe, Oriṣa nla ni Diana ti ara Efesu.

35. Nigbati akọwe ilu si mu ki ijọ enia dakẹ, o ni, Ẹnyin ará Efesu, tali ẹniti o wà ti kò mọ̀ pe, ilu ara Efesu ni iṣe olusin Diana oriṣa nla, ati ti ere ti o ti ọdọ Jupiteri bọ́ silẹ?

36. Njẹ bi a ko ti le sọrọ odi si nkan wọnni, o yẹ ki ẹ dakẹ, ki ẹnyin ki o máṣe fi iwara ṣe ohunkohun.

37. Nitoriti ẹnyin mu awọn ọkunrin wọnyi wá, nwọn kò kó ile oriṣa, bẹ̃ni nwọn kò sọrọ-odi si oriṣa wa.

38. Njẹ nitorina bi Demetriu, ati awọn oniṣọnà ti o wà pẹlu rẹ̀, ba li ọ̀rọ kan si ẹnikẹni, ile-ẹjọ ṣí silẹ, awọn onidajọ si mbẹ: jẹ ki nwọn ki o lọ ifi ara wọn sùn.

39. Ṣugbọn bi ẹ ba nwadi ohun kan nipa ọ̀ran miran, a ó pari rẹ̀ ni ajọ ti o tọ́.

40. Nitori awa sá wà li ewu ati pè bi lẽrè nitori ariwo oni yi, kò sa nidi, ati nitori eyi awa kì yio le dahun fun iwọjọ yi.

41. Nigbati o si ti sọ bẹ̃ tan, o tú ijọ na ká.

Iṣe Apo 19