14. Ati obinrin kan ti orukọ rẹ̀ ijẹ Lidia, elesè àluko, ara ilu Tiatira, ẹniti o nsìn Ọlọrun, o gbọ́ ọ̀rọ wa: ọkàn ẹniti Oluwa ṣí, fetísi ohun ti a ti ẹnu Paulu sọ.
15. Nigbati a si baptisi rẹ̀, ati awọn ará ile rẹ̀, o bẹ̀ wa, wipe, Bi ẹnyin ba kà mi li olõtọ si Oluwa, ẹ wá si ile mi, ki ẹ si wọ̀ nibẹ̀. O si rọ̀ wa.
16. O si ṣe, bi awa ti nlọ si ibi adura na, ọmọbinrin kan ti o li ẹmi afọṣẹ, pade wa, ẹniti o fi afọṣẹ mu ère pipọ fun awọn oluwa rẹ̀ wá:
17. On na li o ntọ̀ Paulu ati awa lẹhin, o si nkigbe, wipe, Awọn ọkunrin wọnyi ni iranṣẹ Ọlọrun Ọgá-ogo, ti nkede ọ̀na igbala fun nyin.
18. O si nṣe eyi li ọjọ pipọ. Ṣugbọn nigbati inu Paulu bajẹ, ti o si yipada, o wi fun ẹmí na pe, Mo paṣẹ fun ọ li orukọ Jesu Kristi kí o jade kuro lara rẹ̀. O si jade ni wakati kanna.