Iṣe Apo 13:29-36 Yorùbá Bibeli (YCE)

29. Bi nwọn si ti mu nkan gbogbo ṣẹ ti a ti kọwe nitori rẹ̀, nwọn si sọ ọ kalẹ kuro lori igi, nwọn si tẹ́ ẹ si ibojì.

30. Ṣugbọn Ọlọrun jí i dide kuro ninu okú:

31. O si farahàn li ọjọ pipọ fun awọn ti o ba a gòke lati Galili wá si Jerusalemu, awọn ti iṣe ẹlẹri rẹ̀ nisisiyi fun awọn enia.

32. Awa si mu ihinrere wá fun nyin, ti ileri tí a ti ṣe fun awọn baba,

33. Bi Ọlọrun ti mu eyi na ṣẹ fun awọn ọmọ wa, nigbati o ji Jesu dide; bi a si ti kọwe rẹ̀ ninu Psalmu keji pe, Iwọ li Ọmọ mi, loni ni mo bí ọ.

34. Ati niti pe o ji i dide kuro ninu oku, ẹniti kì yio tun pada si ibajẹ mọ́, o wi bayi pe, Emi ó fun nyin ni ore mimọ́ Dafidi, ti o daju.

35. Nitori o si wi ninu Psalmu miran pẹlu pe, Iwọ kì yio jẹ ki Ẹni Mimọ́ rẹ ri idibajẹ.

36. Nitori lẹhin igba ti Dafidi sin iran rẹ̀ tan bi ifẹ Ọlọrun, o sùn, a si tẹ́ ẹ tì awọn baba rẹ̀, o si ri idibajẹ.

Iṣe Apo 13