10. Ebi si pa a gidigidi, on iba si jẹun: ṣugbọn nigbati nwọn npèse, o bọ si ojuran,
11. O si ri ọrun ṣí, ohun elo kan si sọkalẹ bi gọgọwú nla, ti a ti igun mẹrẹrin, sọkalẹ si ilẹ.
12. Ninu rẹ̀ li olorijorí ẹranko ẹlẹsẹ mẹrin wà, ati ohun ti nrakò li aiye ati ẹiyẹ oju ọrun.
13. Ohùn kan si fọ̀ si i pe, Dide, Peteru; mã pa ki o si mã jẹ.
14. Ṣugbọn Peteru dahùn pe, Agbẹdọ, Oluwa; nitori emi kò jẹ ohun èwọ ati alaimọ́ kan ri.
15. Ohùn kan si tún fọ̀ si i lẹkeji pe, Ohun ti Ọlọrun ba ti wẹ̀nu, iwọ máṣe pè e li èwọ mọ́.
16. Eyi si ṣe li ẹrinmẹta: lojukanna a si gbé ohun elo na pada lọ soke ọrun.
17. Bi o si ti ngọ́ Peteru ninu ara rẹ̀ bi a ba ti mọ̀ iran ti on ri yi si, si wo o, awọn ọkunrin ti a rán ti ọdọ Korneliu wá de, nwọn mbère ile Simoni, nwọn duro li ẹnu-ọ̀na,
18. Nwọn nahùn bère bi Simoni ti a npè ni Peteru, wọ̀ nibẹ.
19. Bi Peteru si ti nronu iran na, Ẹmí wi fun u pe, Wo o, awọn ọkunrin mẹta nwá ọ.
20. Njẹ dide, sọkalẹ ki o si ba wọn lọ, máṣe kọminu ohunkohun: nitori emi li o rán wọn.
21. Nigbana ni Peteru sọkalẹ tọ̀ awọn ọkunrin ti a rán si i lati ọdọ Korneliu wá; o ni, Wo o, emi li ẹniti ẹnyin nwá: ere idi rẹ̀ ti ẹ fi wá?