1. Sam 4:4-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Bẹli awọn enia si ranṣẹ si Ṣilo, pe ki nwọn gbe lati ibẹ wá apoti majẹmu Oluwa awọn ọmọ-ogun ẹniti o joko larin awọn kerubu: ati awọn ọmọ Eli mejeji, Hofni ati Finehasi, wà nibẹ pẹlu apoti majẹmu Ọlọrun.

5. Nigbati apoti majẹmu Oluwa de budo, gbogbo Israeli si ho yè, tobẹ̃ ti ilẹ mì.

6. Nigbati awọn Filistini si gbọ́ ohùn ariwo na, nwọn si wipe, Ohùn ariwo nla kili eyi ni budo awọn Heberu? O si wa ye wọn pe, apoti majẹmu Oluwa li o de budo.

7. Ẹ̀ru si ba awọn Filistini, nwọn si wipe, Ọlọrun wọ budo. Nwọn si wipe, Awa gbe! nitoripe iru nkan bayi kò si ri.

8. A gbe! tani yio gbà wa lọwọ Ọlọrun alagbara wọnyi? awọn wọnyi li Ọlọrun ti o fi gbogbo ipọnju pọn Egipti loju li aginju.

9. Ẹ jẹ alagbara, ẹ ṣe bi ọkunrin, ẹnyin Filistini, ki ẹnyin máṣe ẹrú fun awọn Heberu, bi nwọn ti nṣe ẹrú nyin ri: Ẹ ṣe bi ọkunrin, ki ẹ si ja.

10. Awọn Filistini si ja, nwọn si lé Israeli, nwọn si sa olukuluku sinu ago rẹ̀: ipani si pọ̀ gidigidi, awọn ẹlẹsẹ ti o ṣubu ninu ogun Israeli jẹ ẹgbãmẹdogun.

11. Nwọn si gbà apoti ẹri Ọlọrun: ọmọ Eli mejeji si kú, Hofni ati Finehasi.

12. Ọkunrin ara Benjamini kan sa lati ogun wá o si wá si Ṣilo lọjọ kanna, ti on ti aṣọ rẹ̀ fifaya, ati erupẹ lori rẹ̀.

1. Sam 4