1. Sam 12:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. SAMUELI wi fun gbogbo Israeli pe, Kiye si i, emi ti gbọ́ ohùn nyin, ninu gbogbo eyi ti ẹnyin wi fun mi, emi si ti fi ẹnikan jọba lori nyin.

2. Si wõ, nisisiyi, ọba na nrìn niwaju nyin: emi si ti di arugbo, mo si hewu; si wõ, awọn ọmọ mi si mbẹ lọdọ nyin: emi ti nrìn niwaju nyìn lati igba ewe mi wá titi o fi di oni yi.

3. Wõ, emi nĩ, jẹri si mi niwaju Oluwa, ati niwaju ẹni ami-ororo rẹ̀: malu tani mo gbà ri? tabi kẹtẹkẹtẹ tani mo gbà ri? tani mo rẹjẹ ri? tani mo jẹ ni ìya ri? tabi lọwọ́ tali emi gbà owo abẹtẹlẹ kan ri lati fi bo ara mi loju? emi o si sãn pada fun nyin.

4. Nwọn si wipe, Iwọ kò rẹ́ wa jẹ ri, bẹ̃ni iwọ kò jẹ ni ni ìya ri, bẹ̃ni iwọ ko gbà nkan lọwọ́ ẹnikẹni wa ri.

5. O si wi fun wọn pe, Oluwa li ẹlẹri si nyin, ati ẹni ami-ororo rẹ̀ ni ẹlẹri loni pe, ẹnyin kò rí nkan lọwọ́ mi. Nwọn si dahùn wipe, On li ẹlẹri.

6. Samueli si wi fun awọn enia na pe, Oluwa li ẹniti o ti yan Mose ati Aaroni, on li ẹni ti o si mu awọn baba nyin goke ti ilẹ Egipti wá.

7. Njẹ nisisiyi ẹ duro jẹ, ki emi ki o le ba nyin sọ̀rọ niwaju Oluwa niti gbogbo iṣẹ ododo Oluwa, eyi ti on ti ṣe fun nyin ati fun awọn baba nyin.

8. Nigbati Jakobu wá si Egipti, ti awọn baba kigbe pe Oluwa, Oluwa si rán Mose ati Aaroni, awọn ẹniti o mu awọn baba nyin ti ilẹ Egypti jade wá, o si mu wọn joko nihinyi.

1. Sam 12