4. Ati ọ̀rọ mi, ati iwasu mi kì iṣe nipa ọ̀rọ ọgbọ́n enia, ti a fi nyi ni lọkàn pada, bikoṣe nipa ifihan ti Ẹmí ati ti agbara:
5. Ki igbagbọ́ nyin ki o máṣe duro ninu ọgbọ́n enia, bikoṣe ninu agbara Ọlọrun.
6. Ṣugbọn awa nsọ̀rọ ọgbọ́n larin awọn ti o pé: ṣugbọn kì iṣe ọgbọ́n ti aiye yi, tabi ti awọn olori aiye yi, ti o di asan:
7. Ṣugbọn awa nsọ̀rọ ọgbọ́n Ọlọrun ni ijinlẹ, ani ọgbọ́n ti o farasin, eyiti Ọlọrun ti làna silẹ ṣaju ipilẹṣẹ aiye fun ogo wa:
8. Eyiti ẹnikẹni ninu awọn olori aiye yi kò mọ̀: nitori ibaṣepe nwọn ti mọ̀ ọ, nwọn kì ba ti kàn Oluwa ogo mọ agbelebu.
9. Ṣugbọn gẹgẹ bi a ti kọ ọ, pe, Ohun ti oju kò ri, ati ti etí kò gbọ, ti kò si wọ ọkàn enia lọ, ohun wọnni ti Ọlọrun ti pèse silẹ fun awọn ti o fẹ ẹ.
10. Ṣugbọn Ọlọrun ti ṣi wọn paya fun wa nipa Ẹmí rẹ̀: nitoripe Ẹmí ni nwadi ohun gbogbo, ani, ohun ijinlẹ ti Ọlọrun.
11. Nitori tani ninu enia ti o mọ̀ ohun enia kan, bikoṣe ẹmí enia ti o wà ninu rẹ̀? bẹ̃ni kò si ẹnikan ti o mọ̀ ohun Ọlọrun, bikoṣe Ẹmí Ọlọrun.
12. Ṣugbọn awa ti gbà, kì iṣe ẹmi ti aiye, bikoṣe Ẹmí ti iṣe ti Ọlọrun; ki awa ki o le mọ̀ ohun ti a fifun wa li ọfẹ lati ọdọ Ọlọrun wá.
13. Ohun na ti awa si nsọ, kì iṣe ninu ọ̀rọ ti ọgbọ́n enia nkọ́ni, ṣugbọn eyiti Ẹmí Mimọ́ fi nkọ́ni; eyiti a nfi ohun Ẹmí we ohun Ẹmí.