21. Solomoni si fi wura ailadàlu bò ile na ninu: o si fi ẹwọ́n wura ṣe oju ibi-mimọ́-julọ, o si fi wura bò o.
22. Gbogbo ile na li o si fi wura bò titi o fi pari gbogbo ile na; ati gbogbo pẹpẹ ti o wà niha ibi-mimọ́-julọ li o fi wura bò.
23. Ati ninu ibi-mimọ́-julọ li o fi igi olifi ṣe kerubu meji, ọkọkan jẹ igbọnwọ mẹwa ni giga.
24. Ati igbọnwọ marun ni apa kerubu kan, ati igbọnwọ marun ni apa kerubu keji; lati igun apakan titi de igun apa-keji jẹ igbọnwọ mẹwa.
25. Igbọnwọ mẹwa si ni kerubu keji: kerubu mejeji jẹ ìwọn kanna ati titobi kanna.
26. Giga kerubu kan jẹ igbọnwọ mẹwa, bẹ̃ni ti kerubu keji.
27. O si fi awọn kerubu sinu ile ti inu lọhun, nwọn si nà iyẹ-apa kerubu na, tobẹ̃ ti iyẹ-apa ọkan si kàn ogiri kan, ati iyẹ-apa kerubu keji si kàn ogiri keji: iyẹ-apa wọn si kàn ara wọn larin ile na.
28. O si fi wura bò awọn kerubu na.