9. Ṣugbọn nisisiyi, máṣe jẹ ki o ṣe alaijiya, nitori ọlọgbọ́n enia ni iwọ, iwọ si mọ̀ ohun ti iwọ o ṣe si i; ṣugbọn ewú ori rẹ̀ ni ki o mu sọkalẹ pẹlu ẹjẹ sinu isa-okú.
10. Dafidi si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i ni ilu Dafidi.
11. Ọjọ ti Dafidi jọba lori Israeli jẹ ogoji ọdun: ni Hebroni o jọba li ọdun meje, ni Jerusalemu o si jọba li ọdun mẹtalelọgbọn.
12. Solomoni si joko lori itẹ Dafidi baba rẹ̀; a si fi idi ijọba rẹ̀ kalẹ gidigidi.
13. Adonijah, ọmọ Haggiti si tọ Batṣeba, iya Solomoni wá, Batṣeba si wipe; Alafia li o ba wá bi? On si wipe, alafia ni.
14. On si wipe, emi ni ọ̀rọ kan ba ọ sọ. On si wipe, Mã wi: