1. ISRAELI, yipadà si Oluwa Ọlọrun rẹ, nitori iwọ ti ṣubu ninu aiṣedẽde rẹ.
2. Mu ọ̀rọ pẹlu nyin, ẹ si yipadà si Oluwa: ẹ wi fun u pe, Mu aiṣedẽde gbogbo kuro, si fi ore-ọfẹ gbà wa: bẹ̃ni awa o fi ọmọ malu ète wa san a fun ọ.
3. Assuru kì yio gbà wa; awa kì yio gùn ẹṣin: bẹ̃ni awa kì yio tun wi mọ fun iṣẹ ọwọ́ wa pe, Ẹnyin li ọlọrun wa: nitori lọdọ rẹ ni alainibaba gbe ri ãnu.
4. Emi o wo ifàsẹhìn wọn sàn, emi o fẹ wọn lọfẹ: nitori ibinu mi yí kuro lọdọ rẹ̀.
5. Emi o dabi ìri si Israeli: on o tanná bi eweko lili; yio si ta gbòngbo rẹ̀ bi Lebanoni.
6. Ẹka rẹ̀ yio tàn, ẹwà rẹ̀ yio si dabi igi olifi, ati õrùn rẹ̀ bi Lebanoni.
7. Awọn ti o ngbe abẹ ojiji rẹ̀ yio padà wá; nwọn o sọji bi ọkà: nwọn o si tanná bi àjara: õrun rẹ̀ yio dabi ọti-waini ti Lebanoni.
8. Efraimu yio wipe, Kili emi ni fi òriṣa ṣe mọ? Emi ti gbọ́, mo si ti kiyesi i: emi dabi igi firi tutù. Lati ọdọ mi li a ti ri èso rẹ.
9. Tali o gbọ́n, ti o lè moye nkan wọnyi? tali o li oye, ti o le mọ̀ wọn? nitori ọ̀na Oluwa tọ́, awọn olododo yio si ma rìn ninu wọn: ṣugbọn awọn alarekọja ni yio ṣubu sinu wọn.