1. ỌLỌRUN si sure fun Noa, ati fun awọn ọmọ rẹ̀, o si wi fun wọn pe, Ẹ ma bí si i, ẹ si ma rẹ̀, ki ẹ si kún aiye.
2. Ati ìbẹru nyin, ati ìfoya nyin, yio ma wà lara gbogbo ẹranko aiye, ati lara gbogbo ẹiyẹ oju-ọrun, ati lara gbogbo ohun ti nrakò ni ilẹ, ati lara gbogbo ẹja okun; ọwọ́ nyin li a fi wọn lé.
3. Gbogbo ohun alãye, ti nrakò, ni yio ma ṣe onjẹ fun nyin; gẹgẹ bi eweko tutu ni mo fi ohun gbogbo fun nyin.
4. Kìki ẹran pẹlu ẹmi rẹ̀, ani ẹ̀jẹ rẹ̀, on li ẹnyin kò gbọdọ jẹ.
5. Nitõtọ ẹ̀jẹ nyin ani ẹmi nyin li emi o si bère; lọwọ gbogbo ẹranko li emi o bère rẹ̀, ati lọwọ enia, lọwọ arakunrin olukuluku enia li emi o bère ẹmi enia.
6. Ẹnikẹni ti o ba ta ẹ̀jẹ enia silẹ, lati ọwọ́ enia li a o si ta ẹ̀jẹ rẹ̀ silẹ: nitoripe li aworan Ọlọrun li o dá enia.
7. Ati ẹnyin, ki ẹnyin ki o ma bí si i; ki ẹ si ma rẹ̀ si i, ki ẹ si ma gbá yìn lori ilẹ, ki ẹ si ma rẹ̀ ninu rẹ̀.
8. Ọlọrun si wi fun Noa, ati fun awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, pe,
9. Ati emi, kiye si i, emi ba nyin dá majẹmu mi, ati awọn irú-ọmọ nyin lẹhin nyin;
10. Ati gbogbo ẹdá alãye ti o wà pẹlu nyin; ti ẹiyẹ, ti ẹran-ọ̀sin, ati ẹranko aiye pélu nyin; lati gbogbo awọn ti o ti inu ọkọ̀ jade, titi o fi de gbogbo ẹranko aiye.
11. Emi o si ba nyin dá majẹmu mi; a ki yio si fi kíkun-omi ké gbogbo ẹdá kuro mọ́; bẹ̃ni kíkun-omi ki yio sí mọ́, lati pa aiye run.