1. NIGBANA ni Josefu wọle, o si sọ fun Farao, o si wipe, Baba mi, ati awọn arakunrin mi ati ọwọ́-ẹran wọn, ati ọwọ́-malu wọn, ati ohun gbogbo ti nwọn ní, nwọn ti ilẹ Kenaani wá; si kiyesi i, nwọn mbẹ ni ilẹ Goṣeni.
2. O si mú marun ninu awọn arakunrin rẹ̀, o si mu wọn duro niwaju Farao.
3. Farao si bi awọn arakunrin rẹ̀ pe, Kini iṣẹ nyin? Nwọn si wi fun Farao pe, Oluṣọ-agutan li awọn iranṣẹ rẹ, ati awa, ati awọn baba wa pẹlu.
4. Nwọn si wi fun Farao pẹlu pe, Nitori ati ṣe atipo ni ilẹ yi li awa ṣe wá; nitori awọn iranṣẹ rẹ kò ní papa-oko tutù fun ọwọ́-ẹran wọn; nitori ti ìyan yi mú gidigidi ni ilẹ Kenaani: njẹ nitorina awa bẹ̀ ọ, jẹ ki awọn iranṣẹ rẹ ki o joko ni ilẹ Goṣeni.
5. Farao si wi fun Josefu pe, Baba rẹ ati awọn arakunrin rẹ tọ̀ ọ wá:
6. Ilẹ Egipti ni yi niwaju rẹ; ninu ãyo ilẹ ni ki o mu baba ati awọn arakunrin rẹ joko; jẹ ki nwọn ki o joko ni ilẹ Goṣeni: bi iwọ ba si mọ̀ ẹnikẹni ti o li ãpọn ninu wọn, njẹ ki iwọ ki o ṣe wọn li olori lori ẹran-ọsin mi.
7. Josefu si mú Jakobu baba rẹ̀ wọle wá, o si mu u duro niwaju Farao: Jakobu si sure fun Farao.
8. Farao si bi Jakobu pe, Ọdún melo li ọjọ́ aiye rẹ?
9. Jakobu si wi fun Farao pe, Ãdoje ọdún li ọjọ́ atipo mi: diẹ ti on ti buburu li ọdún ọjọ́ aiye mi jẹ́, nwọn kò si ti idé ọdún ọjọ́ aiye awọn baba mi li ọjọ́ atipo wọn.
10. Jakobu si sure fun Farao, o si jade kuro niwaju Farao.
11. Josefu si fi baba rẹ̀ ati awọn arakunrin rẹ̀ joko, o si fun wọn ni iní ni ilẹ Egipti, ni ibi ãyo ilẹ, ni ilẹ Ramesesi, bi Farao ti pa li aṣẹ.
12. Josefu si fi onjẹ bọ́ baba rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo ile baba rẹ̀ gẹgẹ bi iye awọn ọmọ wọn.
13. Onjẹ kò si sí ni gbogbo ilẹ; nitori ti ìyan na mú gidigidi, tobẹ̃ ti ilẹ Egipti ati gbogbo ilẹ Kenaani gbẹ nitori ìyan na.