Gẹn 45:5-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Njẹ nisisiyi, ẹ máṣe binujẹ, ki ẹ má si ṣe binu si ara nyin, ti ẹnyin tà mi si ihin: nitori pe, Ọlọrun li o rán mi siwaju nyin lati gbà ẹmi là.

6. Lati ọdún meji yi ni ìyan ti nmú ni ilẹ: o si tun kù ọdún marun si i, ninu eyiti a ki yio ni itulẹ tabi ikorè.

7. Ọlọrun si rán mi siwaju nyin lati da irú-ọmọ si fun nyin lori ilẹ, ati lati fi ìgbala nla gbà ẹmi nyin là.

8. Njẹ nisisiyi, ki iṣe ẹnyin li o rán mi si ihin, bikoṣe Ọlọrun: o si ti fi mi ṣe baba fun Farao, ati oluwa gbogbo ile rẹ̀, ati alakoso gbogbo ilẹ Egipti.

9. Ẹ yara ki ẹ si goke tọ̀ baba mi lọ, ki ẹ si wi fun u pe, Bayi ni Josefu ọmọ rẹ wipe, Ọlọrun fi mi jẹ́ oluwa gbogbo Egipti: sọkalẹ tọ̀ mi wá, má si ṣe duro.

10. Iwọ o si joko ni ilẹ Goṣeni, iwọ o si wà leti ọdọ mi, iwọ, ati awọn ọmọ rẹ, ati awọn ọmọ ọmọ rẹ, ati ọwọ-ẹran rẹ, ati ọwọ́-malu rẹ, ati ohun gbogbo ti iwọ ní.

11. Nibẹ̀ li emi o si ma bọ́ ọ; nitori ọdún ìyan kù marun si i; ki iwọ, ati awọn ara ile rẹ, ati ohun gbogbo ti iwọ ní, ki o má ba ri ipọnju.

12. Si kiyesi i, oju nyin, ati oju Benjamini arakunrin mi ri pe, ẹnu mi li o nsọ̀rọ fun nyin.

13. Ki ẹnyin ki o si ròhin gbogbo ogo mi ni Egipti fun baba mi, ati ti ohun gbogbo ti ẹnyin ri; ki ẹnyin ki o si yara, ki ẹ si mú baba mi sọkalẹ wá ihin.

14. O si rọ̀mọ́ Benjamini arakunrin rẹ̀ li ọrùn, o si sọkun; Benjamini si sọkun li ọrùn rẹ̀.

15. O si fi ẹnu kò gbogbo awọn arakunrin rẹ̀ li ẹnu, o si sọkun si wọn lara: lẹhin eyini li awọn arakunrin rẹ̀ bá a sọ̀rọ.

16. A si gbọ́ ìhin na ni ile Farao pe, awọn arakunrin Josefu dé: o si dùn mọ́ Farao ati awọn iranṣẹ rẹ̀.

17. Farao si wi fun Josefu pe, Wi fun awọn arakunrin rẹ, Eyi ni ki ẹ ṣe; ẹ dì ẹrù lé ẹranko nyin, ki ẹ si lọ si ilẹ Kenaani;

18. Ẹ si mú baba nyin, ati awọn ara ile nyin, ki ẹ si tọ̀ mi wá; emi o si fun nyin li ohun rere ilẹ Egipti, ẹnyin o si ma jẹ ọrá ilẹ yi.

19. Njẹ a fun ọ li aṣẹ, eyi ni ki ẹ ṣe; ẹ mú kẹkẹ́-ẹrù lati ilẹ Egipti fun awọn ọmọ wẹrẹ nyin, ati fun awọn aya nyin, ki ẹ si mú baba nyin, ki ẹ si wá.

Gẹn 45