9. Lọdọ ẹnikẹni ninu awọn iranṣẹ rẹ ti a ba ri i, ki o kú, ati awa pẹlu ki a di ẹrú oluwa mi.
10. O si wipe, Njẹ ki o si ri bẹ̃ gẹgẹ bi ọ̀rọ nyin: ẹniti a ba ri i li ọwọ́ rẹ̀ on ni yio di ẹrú mi, ẹnyin o si ṣe alailẹṣẹ.
11. Nigbana ni olukuluku nwọn yara sọ̀ àpo rẹ̀ kalẹ, olukuluku nwọn si tú àpo rẹ̀.
12. O si nwá a kiri, o bẹ̀rẹ lati ẹgbọ́n wá, o si pin lọdọ abikẹhin: a si ri ago na ninu àpo Benjamini.
13. Nigbana ni nwọn fà aṣọ wọn ya olukuluku si dì ẹrù lé kẹtẹkẹtẹ rẹ̀, nwọn si pada lọ si ilu.
14. Ati Judah ati awọn arakunrin rẹ̀ wá si ile Josefu; on sa wà nibẹ̀: nwọn si wolẹ niwaju rẹ̀.
15. Josefu si wi fun wọn pe, Iwa kili eyiti ẹnyin hù yi? ẹnyin kò mọ̀ pe irú enia bi emi a ma mọ̀ran nitõtọ?
16. Judah si wipe, Kili a o wi fun oluwa mi? kili a o fọ̀? tabi awa o ti ṣe wẹ̀ ara wa mọ́? Ọlọrun ti hú ẹ̀ṣẹ awọn iranṣẹ rẹ jade: wò o, awa di ẹrú oluwa mi, ati awa, ati ẹniti a ri ago na li ọwọ́ rẹ̀ pẹlu.
17. On si wipe, Ki a má ri pe emi o ṣe bẹ̃: ṣugbọn ọkunrin na li ọwọ́ ẹniti a ri ago na, on ni yio ṣe ẹrú mi; bi o ṣe ti ẹnyin, ẹ goke tọ̀ baba nyin lọ li alafia.