Judah si wipe, Kili a o wi fun oluwa mi? kili a o fọ̀? tabi awa o ti ṣe wẹ̀ ara wa mọ́? Ọlọrun ti hú ẹ̀ṣẹ awọn iranṣẹ rẹ jade: wò o, awa di ẹrú oluwa mi, ati awa, ati ẹniti a ri ago na li ọwọ́ rẹ̀ pẹlu.