1. O SI fi aṣẹ fun iriju ile rẹ̀, wipe, Fi onjẹ kún inu àpo awọn ọkunrin wọnyi, ìwọn ti nwọn ba le rù, ki o si fi owo olukuluku si ẹnu àpo rẹ̀.
2. Ki o si fi ago mi, ago fadaka nì, si ẹnu àpo abikẹhin, ati owo ọkà rẹ̀. O si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ ti Josefu ti sọ.
3. Bi ojúmọ si ti mọ́, a si rán awọn ọkunrin na lọ, awọn ati awọn kẹtẹkẹtẹ wọn.
4. Nigbati nwọn si jade kuro ni ilu na, ti nwọn kò si jìna, Josefu wi fun iriju rẹ̀ pe, Dide, lepa awọn ọkunrin na; nigbati iwọ ba si bá wọn, wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi fi buburu san rere?
5. Ninu eyi ki oluwa mi ima mu, eyiti o si fi nmọ̀ran? ẹnyin ṣe buburu li eyiti ẹnyin ṣe yi.
6. O si lé wọn bá, o si sọ ọ̀rọ wọnyi fun wọn.
7. Nwọn si wi fun u pe, Ẽṣe ti oluwa mi fi sọ irú ọ̀rọ wọnyi? Ki a má ri pe awọn ọmọ-ọdọ rẹ ṣe bi irú nkan wọnyi.
8. Kiyesi i, owo ti awa ri li ẹnu àpo wa, awa si tun mú pada fun ọ lati ilẹ Kenaani wá: bawo li awa o ṣe jí fadaka tabi wurà ninu ile oluwa rẹ?
9. Lọdọ ẹnikẹni ninu awọn iranṣẹ rẹ ti a ba ri i, ki o kú, ati awa pẹlu ki a di ẹrú oluwa mi.
10. O si wipe, Njẹ ki o si ri bẹ̃ gẹgẹ bi ọ̀rọ nyin: ẹniti a ba ri i li ọwọ́ rẹ̀ on ni yio di ẹrú mi, ẹnyin o si ṣe alailẹṣẹ.
11. Nigbana ni olukuluku nwọn yara sọ̀ àpo rẹ̀ kalẹ, olukuluku nwọn si tú àpo rẹ̀.
12. O si nwá a kiri, o bẹ̀rẹ lati ẹgbọ́n wá, o si pin lọdọ abikẹhin: a si ri ago na ninu àpo Benjamini.
13. Nigbana ni nwọn fà aṣọ wọn ya olukuluku si dì ẹrù lé kẹtẹkẹtẹ rẹ̀, nwọn si pada lọ si ilu.