Gẹn 42:19-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

19. Bi ẹnyin ba ṣe olõtọ enia, ki a mú ọkan ninu awọn arakunrin nyin dè ni ile túbu nyin: ẹ lọ, ẹ mú ọkà lọ nitori ìyan ile nyin.

20. Ṣugbọn ẹ mú arakunrin nyin abikẹhin fun mi wá; bẹ̃li a o si mọ̀ ọ̀rọ nyin li otitọ, ẹ ki yio si kú. Nwọn si ṣe bẹ̃.

21. Nwọn si wi fun ara wọn pe, Awa jẹbi nitõtọ nipa ti arakunrin wa, niti pe, a ri àrokan ọkàn rẹ̀, nigbati o bẹ̀ wa, awa kò si fẹ́ igbọ́; nitorina ni iyọnu yi ṣe bá wa.

22. Reubeni si da wọn li ohùn pe, Emi kò wi fun nyin pe, Ẹ máṣe ṣẹ̀ si ọmọde na; ẹ kò si fẹ̀ igbọ́? si wò o, nisisiyi, a mbère ẹ̀jẹ rẹ̀.

23. Nwọn kò si mọ̀ pe Josefu gbède wọn; nitori gbedegbẹyọ li o fi mba wọn sọ̀rọ.

24. O si yipada kuro lọdọ wọn, o si sọkun; o si tun pada tọ̀ wọn wá, o si bá wọn sọ̀rọ, o si mú Ṣimeoni ninu wọn, o si dè e li oju wọn.

25. Nigbana ni Josefu paṣẹ ki nwọn fi ọkà kún inu àpo wọn, ki nwọn si mú owo olukuluku pada sinu àpo rẹ̀, ki nwọn ki o si fun wọn li onjẹ ọ̀na; bayi li o si ṣe fun wọn.

26. Nwọn si dì ọkà lé kẹtẹkẹtẹ wọn, nwọn si lọ kuro nibẹ̀.

27. Bi ọkan ninu wọn si ti tú àpo rẹ̀ ni ile-èro lati fun kẹtẹkẹtẹ rẹ̀ li onjẹ, o kofiri owo rẹ̀; si wò o, o wà li ẹnu àpo rẹ̀.

28. O si wi fun awọn arakunrin rẹ̀ pe, Nwọn mú owo mi pada; si wò o, o tilẹ wà li àpo mi: àiya si fò wọn, ẹ̀ru si bà wọn, nwọn nwi fun ara wọn pe, Kili eyiti Ọlọrun ṣe si wa yi?

Gẹn 42