Gẹn 4:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ADAMU si mọ̀ Efa aya rẹ̀; o si loyun, o si bí Kaini, o si wipe, Mo ri ọkunrin kan gbà lọwọ OLUWA.

2. O si bí Abeli arakunrin rẹ̀. Abeli a si ma ṣe oluṣọ-agutan, ṣugbọn Kaini a ma ṣe aroko.

3. O si ṣe, li opin ọjọ́ wọnni ti Kaini mu ọrẹ ninu eso ilẹ fun OLUWA wá.

4. Ati Abeli, on pẹlu mu ninu akọbi ẹran-ọ̀sin ani ninu awọn ti o sanra. OLUWA si fi ojurere wò Abeli ati ọrẹ rẹ̀;

5. Ṣugbọn Kaini ati ọrẹ rẹ̀ ni kò nãni. Kaini si binu gidigidi, oju rẹ̀ si rẹ̀wẹsi.

6. OLUWA si bi Kaini pe, Ẽṣe ti inu fi mbi ọ? ẽ si ti ṣe ti oju rẹ̀ fi rẹ̀wẹsi?

7. Bi iwọ ba ṣe rere, ara ki yio ha yá ọ? bi iwọ kò ba si ṣe rere, ẹ̀ṣẹ ba li ẹnu-ọ̀na, lọdọ rẹ ni ifẹ rẹ̀ yio ma fà si, iwọ o si ma ṣe alakoso rẹ̀.

8. Kaini si ba Abeli arakunrin rẹ̀ sọ̀rọ: o si ṣe, nigbati nwọn wà li oko, Kaini dide si Abeli arakunrin rẹ̀, o si lù u pa.

9. OLUWA si wi fun Kaini pe, Nibo ni Abeli arakunrin rẹ wà? O si wipe, Emi kò mọ̀; emi iṣe olutọju arakunrin mi bi?

10. O si wipe, Kini iwọ ṣe nì? Ohùn ẹ̀jẹ arakunrin rẹ nkigbe pè mi lati inu ilẹ wá.

11. Njẹ nisisiyi a fi ọ ré lori ilẹ, ti o yanu rẹ̀ gbà ẹ̀jẹ arakunrin rẹ lọwọ rẹ.

12. Nigbati iwọ ba ro ilẹ, lati isisiyi lọ, ki yio fi agbara rẹ̀ so eso fun ọ mọ; isansa ati alarinkiri ni iwọ o ma jẹ li aiye.

Gẹn 4