Gẹn 32:8-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. O si wipe, bi Esau ba kàn ẹgbẹ kan, ti o si kọlù u, njẹ ẹgbẹ keji ti o kù yio là.

9. Jakobu si wipe, Ọlọrun Abrahamu baba mi, ati Ọlọrun Isaaki baba mi, OLUWA ti o wi fun mi pe, pada lọ si ilẹ rẹ, ati sọdọ awọn ara rẹ, emi o si ṣe ọ ni rere:

10. Emi kò yẹ si kikini ninu gbogbo ãnu, ati ninu gbogbo otitọ, ti iwọ fihàn fun ọmọ-ọdọ rẹ, nitori pe, kìki ọpá mi ni mo fi kọja Jordani yi; nisisiyi emi si di ẹgbẹ meji.

11. Emi bẹ̀ ọ, gbà mi lọwọ arakunrin mi, lọwọ Esau: nitori ti mo bẹ̀ru rẹ̀, ki o má ba wá lati kọlù mi, ti iya ti ọmọ.

12. Iwọ si wipe, Nitõtọ emi o ṣe ọ ni rere, emi o si ṣe irú-ọmọ rẹ bi iyanrin okun, ti a kò le kà fun ọ̀pọlọpọ.

13. O si sùn nibẹ̀ li alẹ ijọ́ na; o si mú ninu ohun ti o tẹ̀ ẹ li ọwọ li ọrẹ fun Esau, arakunrin rẹ̀;

14. Igba ewurẹ, on ogún obukọ, igba agutan, on ogún àgbo,

15. Ọgbọ̀n ibakasiẹ ti o ní wàra, pẹlu awọn ọmọ wọn, ogojì abo-malu on akọ-malu mẹwa, ogún abo-kẹtẹkẹtẹ, on ọmọ-kẹtẹkẹtẹ mẹwa.

16. O si fi wọn lé ọwọ́ awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, ni ọ̀wọ́ kọkan; o si wi fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, Ẹnyin ṣaju mi, ki ẹ si fi àlàfo si agbedemeji ọwọ́-ọwọ.

17. O si fi aṣẹ fun eyiti o tète ṣaju wipe, Nigbati Esau, arakunrin mi, ba pade rẹ, ti o si bi ọ wipe, Ti tani iwọ? nibo ni iwọ si nrè? ati ti tani wọnyi niwaju rẹ?

Gẹn 32