Gẹn 3:5-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Nitori Ọlọrun mọ̀ pe, li ọjọ́ ti ẹnyin ba jẹ ninu rẹ̀, nigbana li oju nyin yio là, ẹnyin o si dabi Ọlọrun, ẹ o mọ̀ rere ati buburu.

6. Nigbati obinrin na si ri pe, igi na dara ni jijẹ, ati pe, o si dara fun oju, ati igi ti a ifẹ lati mu ni gbọ́n, o mu ninu eso rẹ̀ o si jẹ, o si fi fun ọkọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, on si jẹ.

7. Oju awọn mejeji si là, nwọn si mọ̀ pe nwọn wà ni ìhoho; nwọn si gán ewe ọpọtọ pọ̀, nwọn si dá ibantẹ fun ara wọn.

8. Nwọn si gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun, o nrìn ninu ọgbà ni itura ọjọ́: Adamu ati aya rẹ̀ si fi ara wọn pamọ́ kuro niwaju OLUWA Ọlọrun lãrin igi ọgbà.

9. OLUWA Ọlọrun si kọ si Adamu, o si wi fun u pe, Nibo ni iwọ wà?

10. O si wipe, Mo gbọ́ ohùn rẹ ninu ọgbà, ẹ̀ru si bà mi, nitori ti mo wà ni ìhoho; mo si fi ara pamọ́.

11. O si wi pe, Tali o wi fun ọ pe iwọ wà ni ìhoho? iwọ ha jẹ ninu igi nì, ninu eyiti mo paṣẹ fun ọ pe iwọ kò gbọdọ jẹ?

12. Ọkunrin na si wipe, Obinrin ti iwọ fi pẹlu mi, on li o fun mi ninu eso igi na, emi si jẹ.

13. OLUWA Ọlọrun si bi obinrin na pe, Ewo ni iwọ ṣe yi? Obinrin na si wipe, Ejò li o tàn mi, mo si jẹ.

14. OLUWA Ọlọrun si wi fun ejò na pe, nitori ti iwọ ti ṣe eyi, a fi iwọ bú ninu gbogbo ẹran ati ninu gbogbo ẹranko igbẹ; inu rẹ ni iwọ o ma fi wọ́, erupẹ ilẹ ni iwọ o ma jẹ li ọjọ́ aiye rẹ gbogbo.

15. Emi o si fi ọta sãrin iwọ ati obinrin na, ati sãrin irú-ọmọ rẹ ati irú-ọmọ rẹ̀: on o fọ́ ọ li ori, iwọ o si pa a ni gigĩsẹ.

16. Fun obinrin na li o wipe, Emi o sọ ipọnju ati iloyun rẹ di pupọ̀; ni ipọnju ni iwọ o ma bimọ; lọdọ ọkọ rẹ ni ifẹ rẹ yio ma fà si, on ni yio si ma ṣe olori rẹ.

Gẹn 3