12. O si lá alá, si kiyesi i, a gbé àkasọ kan duro lori ilẹ, ori rẹ̀ si de oke ọrun: si kiyesi i, awọn angeli Ọlọrun ngoke, nwọn si nsọkalẹ lori rẹ̀.
13. Si kiyesi i, OLUWA duro loke rẹ̀, o si wi pe, Emi li OLUWA, Ọlọrun Abrahamu baba rẹ, ati Ọlọrun Isaaki; ilẹ ti iwọ dubulẹ le nì, iwọ li emi o fi fun, ati fun irú-ọmọ rẹ.
14. Irú-ọmọ rẹ yio si ri bi erupẹ̀ ilẹ, iwọ o si tàn kalẹ si ìha ìwọ-õrùn, ati si ìha ìla-õrùn, ati si ìha ariwa, ati si ìha gusù: ninu rẹ, ati ninu irú-ọmọ rẹ li a o bukún fun gbogbo ibatan aiye.
15. Si kiyesi i, emi wà pẹlu rẹ, emi o sì pa ọ mọ́ ni ibi gbogbo ti iwọ nlọ, emi o si tun mu ọ bọ̀wá si ilẹ yi; nitori emi ki yio kọ̀ ọ silẹ, titi emi o fi ṣe eyiti mo wi fun ọ tan.
16. Jakobu si jí li oju-orun rẹ̀, o si wipe, OLUWA mbẹ nihinyi nitõtọ; emi kò si mọ̀.
17. Ẹrù si bà a, o si wipe, Ihinyi ti li ẹ̀ru tó! eyi ki iṣe ibi omiran, bikoṣe ile Ọlọrun, eyi si li ẹnubode ọrun.
18. Jakobu si dide ni kutukutu owurọ̀, o si mu okuta ti o fi ṣe irọri rẹ̀, o si fi lelẹ fun ọwọ̀n, o si ta oróro si ori rẹ̀.
19. O si pè orukọ ibẹ̀ na ni Beteli: ṣugbọn Lusi li orukọ ilu na ri.
20. Jakobu si jẹ́ ẹjẹ́ wipe, Bi Ọlọrun ba pẹlu mi, ti o si pa mi mọ́ li ọ̀na yi ti emi ntọ̀, ti o si fun mi li ohun jijẹ, ati aṣọ bibora,
21. Ti mo si pada wá si ile baba mi li alafia; njẹ OLUWA ni yio ma ṣe Ọlọrun mi.
22. Okuta yi, ti mo fi lelẹ ṣe ọwọ̀n ni yio si ṣe ile Ọlọrun: ati ninu ohun gbogbo ti iwọ o fi fun mi, emi o si fi idamẹwa rẹ̀ fun ọ.