Gẹn 28:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ISAAKI si pè Jakobu, o si sùre fun u, o si kìlọ fun u, o si wi fun u pe, Iwọ kò gbọdọ fẹ́ aya ninu awọn ọmọbinrin Kenaani.

2. Dide, lọ si Padan-aramu, si ile Betueli, baba iya rẹ; ki iwọ ki o si fẹ́ aya lati ibẹ̀ wá ninu awọn ọmọbinrin Labani, arakunrin iya rẹ.

3. Ki Ọlọrun Olodumare ki o gbè ọ, ki o si mu ọ bisi i, ki o si mu ọ rẹ̀ si i, ki iwọ ki o le di ọ̀pọlọpọ enia.

4. Ki o si fi ibukún Abrahamu fun ọ, fun iwọ ati fun irú-ọmọ rẹ pẹlu rẹ; ki iwọ ki o le ni ilẹ na ninu eyiti iwọ nṣe atipo, ti Ọlọrun fi fun Abrahamu.

5. Isaaki si rán Jakobu lọ: o si lọ si Padan-aramu si ọdọ Labani, ọmọ Betueli, ara Siria, arakunrin Rebeka, iya Jakobu on Esau.

6. Nigbati Esau ri pe Isaaki sure fun Jakobu ti o si rán a lọ si Padan-aramu, lati fẹ́ aya lati ibẹ̀; ati pe bi o ti sure fun u, o si kìlọ fun u wipe, iwọ kò gbọdọ fẹ́ aya ninu awọn ọmọbinrin Kenaani;

7. Ati pe Jakobu gbọ́ ti baba ati ti iya rẹ̀, ti o si lọ si Padan-aramu:

8. Nigbati Esau ri pe awọn ọmọbinrin Kenaani kò wù Isaaki baba rẹ̀;

9. Nigbana ni Esau tọ̀ Iṣmaeli lọ, o si fẹ́ Mahalati ọmọbinrin Iṣmaeli, ọmọ Abrahamu, arabinrin Nebajotu, kún awọn obinrin ti o ni.

10. Jakobu si jade kuro lati Beer-ṣeba lọ, o si lọ si ìha Harani.

11. O si de ibi kan, o duro nibẹ̀ li oru na, nitori õrùn wọ̀; o si mu ninu okuta ibẹ̀ na, o fi ṣe irọri rẹ̀, o si sùn nibẹ̀ na.

12. O si lá alá, si kiyesi i, a gbé àkasọ kan duro lori ilẹ, ori rẹ̀ si de oke ọrun: si kiyesi i, awọn angeli Ọlọrun ngoke, nwọn si nsọkalẹ lori rẹ̀.

Gẹn 28