1. ABRAHAMU si tun fẹ́ aya kan, orukọ rẹ̀ a ma jẹ Ketura.
2. O si bí Simrani, ati Jokṣani, ati Medani, ati Midiani, ati Iṣbaku, ati Ṣua fun u.
3. Jokṣani si bí Ṣeba, ati Dedani. Awọn ọmọ Dedani si ni Aṣurimu, ati Letuṣimu, ati Leumimu.
4. Ati awọn ọmọ Midiani; Efa, ati Eferi, ati Hanoku, ati Abida, ati Eldaa. Gbogbo awọn wọnyi li ọmọ Ketura.
5. Abrahamu si fi gbogbo ohun ti o ni fun Isaaki.
6. Ṣugbọn awọn ọmọ àle ti Abrahamu ni, Abrahamu bùn wọn li ẹ̀bun, o si rán wọn lọ kuro lọdọ Isaaki, ọmọ rẹ̀, nigbati o wà lãye, si ìha ìla-õrùn, si ilẹ ìla-õrùn.
7. Iwọnyi si li ọjọ́ ọdún aiye Abrahamu ti o wà, arun dí lọgọsan ọdún.
8. Abrahamu si jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ, o si kú li ogbologbo, arugbo, o kún fun ọjọ́; a si kó o jọ pẹlu awọn enia rẹ̀.
9. Awọn ọmọ rẹ̀, Isaaki ati Iṣmaeli si sin i ni ihò Makpela, li oko Efroni, ọmọ Sohari enia Hitti, ti o wà niwaju Mamre;
10. Oko ti Abrahamu rà lọwọ awọn ọmọ Heti: nibẹ̀ li a gbé sin Abrahamu, ati Sara, aya rẹ̀.
11. O si ṣe lẹhin ikú Abrahamu li Ọlọrun bukún fun Isaaki, ọmọ rẹ̀; Isaaki si joko leti kanga Lahai-roi.
12. Iwọnyi si ni iran Iṣmaeli, ọmọ Abrahamu, ti Hagari, ara Egipti, ọmọbinrin ọdọ Sara bí fun Abrahamu:
13. Iwọnyi si li orukọ awọn ọmọkunrin Iṣmaeli, nipa orukọ wọn, ni iran idile wọn: akọ́bi Iṣmaeli, Nebajotu; ati Kedari, ati Adbeeli, ati Mibsamu,
14. Ati Miṣma, ati Duma, ati Masa;
15. Hadari, ati Tema, Jeturi, Nafiṣi, ati Kedema:
16. Awọn wọnyi li awọn ọmọ Iṣmaeli, iwọnyi si li orukọ wọn, li ori-ori ilu wọn, li ori-ori ile odi wọn; ijoye mejila li orilẹ-ède wọn.
17. Iwọnyi si li ọdún aiye Iṣmaeli, ẹtadilogoje ọdún: o si jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ, o si kú; a si kó o jọ pọ̀ pẹlu awọn enia rẹ.