Gẹn 21:14-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Abrahamu si dide ni kutukutu owurọ̀, o mu àkara ati ìgo omi kan, o fi fun Hagari, o gbé e lé e li ejika, ati ọmọ na, o si lé e jade: on si lọ, o nrìn kakiri ni ijù Beer-ṣeba.

15. Omi na si tán ninu ìgo, o si sọ̀ ọmọ na si abẹ ìgboro kan.

16. O si lọ, o joko kọju si i, li ọ̀na jijìn rére, o tó bi itafasi kan: nitori ti o wipe, Ki emi má ri ikú ọmọ na. O si joko kọju si i, o gbé ohùn rẹ̀ soke, o nsọkun.

17. Ọlọrun si gbọ́ ohùn ọmọdekunrin na: angeli Ọlọrun si pè Hagari lati ọrun wá, o bi i pe, Kili o ṣe ọ, Hagari? máṣe bẹ̀ru; nitori ti Ọlọrun ti gbọ́ ohùn ọmọdekunrin na nibiti o gbé wà.

18. Dide, gbé ọmọdekunrin na, ki o si dì i mu; nitori ti emi o sọ ọ di orilẹ-ède nla.

19. Ọlọrun si ṣí i li oju, o si ri kanga omi kan; o lọ, o si pọnmi kún ìgo na, o si fi fun ọmọdekunrin na mu.

20. Ọlọrun si wà pẹlu ọmọdekunrin na; o si dàgba, o si joko ni ijù, o di tafatafa.

21. O si joko ni ijù Parani: iya rẹ̀ si fẹ́ obinrin fun u lati ilẹ Egipti wá.

22. O si ṣe li akokò na, ni Abimeleki ati Fikoli, olori ogun rẹ̀, wi fun Abrahamu pe, Ọlọrun pẹlu rẹ ni gbogbo ohun ti iwọ nṣe.

23. Njẹ nisisiyi fi Ọlọrun bura fun mi nihinyi pe iwọ ki yio ṣe ẹ̀tan si mi, tabi si ọmọ mi, tabi si ọmọ-ọmọ mi: ṣugbọn gẹgẹ bi iṣeun ti mo ṣe si ọ, bẹ̃ni iwọ o si ṣe si mi, ati si ilẹ ti iwọ ti ṣe atipo ninu rẹ̀.

24. Abrahamu si wipe, emi o bura.

25. Abrahamu si ba Abimeleki wi nitori kanga omi kan, ti awọn ọmọ-ọdọ Abimeleki fi agbara gbà.

26. Abimeleki si wipe, emi kò mọ̀ ẹniti o ṣe nkan yi: bẹ̃ni iwọ kò sọ fun mi, bẹ̃li emi kò gbọ́, bikoṣe loni.

27. Abrahamu si mu agutan, ati akọmalu, o fi wọn fun Abimeleki; awọn mejeji si dá majẹmu.

Gẹn 21