1. NIGBANA li awa pada, a si lọ soke li ọ̀na Baṣani: Ogu ọba Baṣani si jade si wa, on ati gbogbo awọn enia rẹ̀, fun ìja ni Edrei.
2. OLUWA si wi fun mi pe, Máṣe bẹ̀ru rẹ̀: nitoripe emi ti fi on, ati gbogbo awọn enia rẹ̀, ati ilẹ rẹ̀, le ọ lọwọ; iwọ o si ṣe si i bi iwọ ti ṣe si Sihoni ọba ọmọ Amori, ti ngbé Heṣboni.
3. Bẹ̃ni OLUWA Ọlọrun wa fi Ogu, ọba Baṣani, ati gbogbo awọn enia rẹ̀, lé wa lọwọ pẹlu: awa si kọlù u titi kò si kù ẹnikan silẹ fun u.
4. Awa si kó gbogbo ilu rẹ̀ ni ìgba na; kò sí ilu kan ti awa kò gbà lọwọ wọn; ọgọta ilu, gbogbo ẹkùn Argobu, ilẹ ọba Ogu ni Baṣani.
5. Gbogbo ilu wọnyi li a mọ odi giga si pẹlu ibode, ati idabu-ẹ̀kun; laikà ọ̀pọlọpọ ilu alailodi.
6. Awa si run wọn patapata, bi awa ti ṣe si Sihoni ọba Heṣboni, ni rirun awọn ọkunrin, obinrin, ati awọn ọmọ wẹ́wẹ patapata, ni ilu na gbogbo.
7. Ṣugbọn gbogbo ohunọ̀sin, ati ikogun ilu wọnni li awa kó ni ikogun fun ara wa.
8. Nigbana li awa gbà li ọwọ́ awọn ọba ọmọ Amori mejeji, ilẹ ti mbẹ ni ìha ẹ̀bá Jordani, lati afonifoji Arnoni lọ dé òke Hermoni;
9. (Awọn ara Sidoni a ma pè Hermoni ni Sirioni, ati awọn ọmọ Amori a si ma pè e ni Seniri;)
10. Gbogbo ilu pẹtẹlẹ̀ na, ati gbogbo Gileadi, ati gbogbo Baṣani, dé Saleka ati Edrei, awọn ilu ilẹ ọba Ogu ni Baṣani.
11. (Ogu ọba Baṣani nikanṣoṣo li o sá kù ninu awọn omirán iyokù; kiyesi i, akete rẹ̀ jẹ́ akete irin; kò ha wà ni Rabba ti awọn ọmọ Ammoni? igbọnwọ mẹsan ni gigùn rẹ̀, igbọnwọ mẹrin si ni ibú rẹ̀, ni igbọnwọ ọkunrin.)
12. Ati ilẹ na yi, ti awa gbà ni ìgbana, lati Aroeri, ti mbẹ lẹba afonifoji Arnoni, ati àbọ òke Gileadi, ati ilu inu rẹ̀, ni mo fi fun awọn ọmọ Reubeni, ati fun awọn ọmọ Gadi:
13. Ati iyokù Gileadi, ati gbogbo Baṣani, ilẹ ọba Ogu, ni mo fi fun àbọ ẹ̀ya Manasse; gbogbo ẹkùn Argobu, pẹlu gbogbo Baṣani. (Ti a ma pè ni ilẹ awọn omirán.
14. Jairi ọmọ Manasse mú gbogbo ilẹ Argobu, dé opinlẹ Geṣuri ati Maakati; o si sọ wọn, ani Baṣan, li orukọ ara rẹ̀, ni Haffotu-jairi titi, di oni.)
15. Mo si fi Gileadi fun Makiri.
16. Ati awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi ni mo fi fun lati Gileadi, ani dé afonifoji Arnoni, agbedemeji afonifoji, ati opinlẹ rẹ̀; ani dé odò Jaboku, ti iṣe ipinlẹ awọn ọmọ Ammoni;
17. Pẹtẹlẹ̀ ni pẹlu, ati Jordani ati opinlẹ rẹ̀, lati Kinnereti lọ titi dé okun pẹtẹlẹ̀, ani Okun Iyọ̀, nisalẹ awọn orisun Pisga ni ìha ìla-õrùn.