2. Àwọn ohun tí o gbọ́ láti ẹnu mi níwájú ọpọlọpọ ẹlẹ́rìí, ni kí o fi lé àwọn olóòótọ́ eniyan lọ́wọ́, àwọn tí ó tó láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn.
3. Farada ìpín tìrẹ ninu ìṣòro gẹ́gẹ́ bí ọmọ-ogun Kristi Jesu.
4. Kò sí ọmọ-ogun tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ tí ó gbọdọ̀ tún tojú bọ àwọn nǹkan ayé yòókù. Àníyàn rẹ̀ kanṣoṣo ni láti tẹ́ ọ̀gágun rẹ̀ lọ́rùn.
5. Kò sí ẹni tí ó bá ń súré ìje tí ó lè gba èrè àfi bí ó bá pa òfin iré ìje mọ́.
6. Àgbẹ̀ tí ń ṣiṣẹ́ lóko ni ó kọ́ ní ẹ̀tọ́ sí ìkórè oko.
7. Gba ohun tí mò ń sọ rò. Oluwa yóo jẹ́ kí ìtumọ̀ rẹ̀ yé ọ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.
8. Ranti Jesu Kristi tí a jí dìde kúrò ninu òkú, tí a bí ninu ìdílé Dafidi. Ìyìn rere tí mò ń waasu nìyí.
9. Ninu iṣẹ́ yìí ni mo ti ń jìyà títí mo fi di ẹlẹ́wọ̀n bí ọ̀daràn. Ṣugbọn kò sí ẹni tí ó lè fi ẹ̀wọ̀n de ọ̀rọ̀ Ọlọrun.
10. Nítorí náà, mo farada ohun gbogbo nítorí àwọn àyànfẹ́, kí àwọn náà lè rí ìgbàlà tí ó wà ninu Kristi Jesu pẹlu ògo tí ó wà títí lae.
11. Òdodo ọ̀rọ̀ nìyí, pé,“Bí a bá bá a kú,a óo wà láàyè pẹlu rẹ̀.
12. Bí a bá faradà á,a óo bá a jọba.Bí a bá sẹ́ ẹ,òun náà yóo sẹ́ wa.
13. Bí àwa kò bá tilẹ̀ ṣe é gbẹ́kẹ̀lé,òun ṣe é gbẹ́kẹ̀lé nígbà gbogbo,nítorí òun kò lè tan ara rẹ̀ jẹ.”