11. Ọlọrun yàn mí láti jẹ́ akéde ati aposteli ati olùkọ́ni.
12. Ìdí nìyí tí mo fi ń jìyà báyìí. Ṣugbọn ojú kò tì mí. Nítorí mo mọ ẹni tí mo gbẹ́kẹ̀lé. Ó sì dá mi lójú pé ó lè pa ìṣúra tí mo fi pamọ́ sí i lọ́wọ́ mọ́ títí di ọjọ́ ńlá náà.
13. Di àpẹẹrẹ ẹ̀kọ́ tí ó yẹ, tí o ti gbà láti ọ̀dọ̀ mi mú, pẹlu igbagbọ ati ìfẹ́ tí ó wà ninu Kristi Jesu.
14. Pa ìṣúra rere náà mọ́ pẹlu agbára Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó ń gbé inú rẹ.
15. O kò ní ṣàìmọ̀ pé gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní agbègbè Esia ti sá kúrò lọ́dọ̀ mi, tí ó fi mọ́ Fugẹlọsi ati Hemogenesi.
16. Kí Oluwa ṣàánú ìdílé Onesiforosi. Kò ní iye ìgbà tí ó ti tù mí ninu, ninu ìṣòro mi. Kò tijú pé ẹlẹ́wọ̀n ni mí.
17. Nígbà tí ó dé Romu, ó fi ìtara wá mi kàn, ó sì rí mi.
18. Kí Oluwa jẹ́ kí ó lè rí àánú rẹ̀ gbà ní ọjọ́ ńlá náà. Iṣẹ́ iranṣẹ tí ó ṣe ní Efesu kò ṣe àjèjì sí ìwọ alára.