Tẹsalonika Keji 1:2-9 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba ati Oluwa Jesu Kristi máa wà pẹlu yín.

3. Ẹ̀yin ará, ó yẹ kí á máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun nígbà gbogbo nítorí yín. Ó tọ́ bẹ́ẹ̀ nítorí pé igbagbọ yín ń tóbi sí i, ìfẹ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan yín sí ara yín sì ń pọ̀ sí i.

4. Àwa fúnra wa ń fọ́nnu nípa yín láàrin àwọn ìjọ Ọlọrun. À ń ròyìn ìfaradà ati igbagbọ yín ninu gbogbo inúnibíni ati ìpọ́njú tí ẹ̀ ń faradà.

5. Ìfaradà yín jẹ́ ẹ̀rí ìdájọ́ òdodo Ọlọrun láti kà yín yẹ fún ìjọba rẹ̀ tí ẹ̀ ń tìtorí rẹ̀ jìyà.

6. Nítorí ó tọ́ lójú Ọlọrun láti fi ìpọ́njú san ẹ̀san fún àwọn tí wọn ń pọn yín lójú,

7. ati láti fún ẹ̀yin tí wọn ń pọ́n lójú, ati àwa náà ní ìsinmi, nígbà tí Oluwa wa, Jesu, bá farahàn láti ọ̀run ninu ọwọ́ iná pẹlu àwọn angẹli tí wọ́n jẹ́ alágbára.

8. Nígbà náà ni yóo gbẹ̀san lára àwọn tí kò mọ Ọlọrun ati àwọn tí kò gba ọ̀rọ̀ ìyìn rere Oluwa wa Jesu.

9. Àwọn yìí ni wọn yóo gba ìdálẹ́bi sí ìparun ayérayé, wọn yóo sì kúrò níwájú Oluwa ati ògo agbára rẹ̀;

Tẹsalonika Keji 1