Samuẹli Kinni 30:19-28 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Kò sí ohun kan tí ó nù, Dafidi gba gbogbo àwọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin rẹ̀ pada, ati gbogbo nǹkan tí àwọn ará Amaleki kó.

20. Ó gba gbogbo àwọn ẹran ọ̀sìn pẹlu. Àwọn eniyan náà sì ń dá àwọn ẹran ọ̀sìn náà jọ níwájú Dafidi, wọ́n ń sọ pé, “Ìkógun Dafidi nìyí.”

21. Dafidi lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn igba (200) eniyan tí àárẹ̀ mú pupọ, tí wọn kò lè kọjá odò, ṣugbọn tí wọ́n dúró lẹ́yìn odò Besori; àwọn náà wá pàdé Dafidi ati àwọn tí wọ́n bá a lọ. Dafidi sì kí wọn dáradára.

22. Àwọn tí wọ́n jẹ́ eniyan burúkú ati òǹrorò láàrin àwọn tí wọ́n bá Dafidi lọ ní, “Nítorí pé wọn kò bá wa lọ, a kò ní fún wọn ninu ìkógun wa tí a gbà pada, àfi aya ati àwọn ọmọ wọn nìkan ni wọ́n lè gbà.”

23. Ṣugbọn Dafidi dáhùn pé, “Ẹ̀yin arakunrin mi, ẹ ẹ̀ gbọdọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí gbogbo ohun tí OLUWA fifún wa. Òun ni ó pa wá mọ́ tí ó sì fún wa ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọmọ ogun tí wọ́n dojú ìjà kọ wá.

24. Kò sí ẹni tí yóo fara mọ́ àbá yín yìí. Gbogbo wa ni a óo jọ pín ìkógun náà dọ́gba-dọ́gba, ati àwọn tí ó lọ ati àwọn tí ó dúró ti ẹrù.”

25. Láti ọjọ́ náà ni ó ti sọ ọ́ di òfin ati ìlànà ní Israẹli, títí di òní olónìí.

26. Nígbà tí Dafidi pada dé Sikilagi, ó fi ẹ̀bùn ranṣẹ sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olórí Juda; ó mú ninu ìkógun náà, ó ní, “Ẹ̀bùn yín nìyí lára ìkógun tí a kó láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀tá OLUWA.”

27. Ó fi ranṣẹ sí àwọn tí wọ́n wà ní Bẹtẹli, ati àwọn tí wọ́n wà ní Ramoti ti Nẹgẹbu, ati Jatiri;

28. ati àwọn tí wọ́n wà ní Aroeri, Sifimoti, ati ní Eṣitemoa;

Samuẹli Kinni 30