12. Ní ọjọ́ náà, n óo ṣe gbogbo ohun tí mo ti sọ pé n óo ṣe sí ìdílé Eli, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin.
13. Mo ti sọ fún un pé n óo jẹ ìdílé rẹ̀ níyà títí lae, nítorí pé àwọn ọmọ rẹ̀ ti ṣe nǹkan burúkú sí mi. Eli mọ̀ pé wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ ṣugbọn kò dá wọn lẹ́kun.
14. Nítorí náà, mo ti búra fún ilé Eli pé, kò sí ẹbọ kan tabi ọrẹ tí ó lè wẹ ẹ̀ṣẹ̀ burúkú náà kúrò laelae.”
15. Samuẹli dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀ títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji. Nígbà tí ó di òwúrọ̀, ó dìde, ó ṣí gbogbo ìlẹ̀kùn ilé OLUWA, ṣugbọn ẹ̀rù ń bà á láti sọ ìran tí ó rí fún Eli.
16. Eli pè é, ó ní, “Samuẹli, ọmọ mi!”Samuẹli dá a lóhùn pé, “Èmi nìyí.”
17. Eli bi í pé, “Kí ni OLUWA wí fún ọ, má fi nǹkankan pamọ́ fún mi. OLUWA yóo ṣe sí ọ jù bí ó ti sọ fún ọ lọ, bí o bá fi nǹkankan pamọ́ fún mi ninu ohun tí ó sọ fún ọ.”
18. Samuẹli bá sọ gbogbo rẹ̀ patapata, kò fi nǹkankan pamọ́ fún un. Eli dáhùn pé, “OLUWA ni, jẹ́ kí ó ṣe bí ó bá ti tọ́ lójú rẹ̀.”