Samuẹli Kinni 2:8-14 BIBELI MIMỌ (BM)

8. OLUWA ń gbé talaka dìde láti ipò ìrẹ̀lẹ̀;ó ń gbé aláìní dìde láti inú òṣì rẹ̀,láti mú wọn jókòó pẹlu àwọn ọmọ ọba,kí wọ́n sì wà ní ipò ọlá.Nítorí pé òun ni ó ni àwọn ìpìlẹ̀ ayé,òun ni ó sì gbé ayé kalẹ̀ lórí wọn.

9. “Yóo pa àwọn olóòótọ́ tí wọ́n jẹ́ tirẹ̀ mọ́,ṣugbọn yóo mú kí àwọn eniyan burúkú parẹ́ ninu òkùnkùn;nítorí pé, kì í ṣe nípa agbára eniyan, ni ẹnikẹ́ni lè fi ṣẹgun.

10. Àwọn ọ̀tá OLUWA yóo parun;OLUWA yóo sán ààrá pa wọ́n láti ojú ọ̀run wá.OLUWA yóo ṣe ìdájọ́ gbogbo ayé,yóo fún ọba rẹ̀ lágbára,yóo sì fún ẹni tí ó yàn ní ìṣẹ́gun.”

11. Lẹ́yìn náà, Elikana pada sí ilé rẹ̀ ní Rama. Ṣugbọn Samuẹli dúró sí Ṣilo, ó ń ṣiṣẹ́ iranṣẹ sin OLUWA, lábẹ́ alufaa Eli.

12. Aláìníláárí ẹ̀dá ni àwọn ọmọ Eli mejeeji. Wọn kò bọ̀wọ̀ fún OLUWA rárá.

13. Ó jẹ́ àṣà àwọn alufaa pé nígbà tí ẹnìkan bá wá rúbọ, iranṣẹ alufaa yóo wá, ti òun ti ọ̀pá irin oníga mẹta tí wọ́n fi ń yọ ẹran lọ́wọ́ rẹ̀. Nígbà tí wọ́n bá ń se ẹran náà lọ́wọ́ lórí iná,

14. yóo ti ọ̀pá irin náà bọ inú ìkòkò ẹran, gbogbo ẹran tí ó bá yọ jáde á jẹ́ ti alufaa. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n máa ń ṣe sí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n bá wá rúbọ ní Ṣilo.

Samuẹli Kinni 2