1. Hana bá gbadura báyìí pé:“Ọkàn mi kún fún ayọ̀ ninu OLUWA,Ó sọ mí di alágbára;mò ń fi àwọn ọ̀tá mi rẹ́rìn-ín,nítorí mò ń yọ̀ pé OLUWA gbà mí là.
2. “Kò sí ẹni mímọ́ bíi OLUWA,kò sí ẹlòmíràn,àfi òun nìkan ṣoṣo.Kò sí aláàbò kan tí ó dàbí Ọlọrun wa.
3. Má sọ̀rọ̀ pẹlu ìgbéraga mọ́,má jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìgbéraga ti ẹnu rẹ jáde,nítorí Ọlọrun tí ó mọ ohun gbogbo ni OLUWA,gbogbo ohun tí ẹ̀dá bá ṣe ni ó sì máa ń gbéyẹ̀wò.
4. Ọrun àwọn alágbára dá,ṣugbọn àwọn aláìlágbára di alágbára.
5. Àwọn tí wọ́n rí oúnjẹ jẹ lájẹyó ríti di ẹni tí ń fi ara wọn ṣọfà nítorí oúnjẹ,ṣugbọn àwọn tí ebi ti ń pa tẹ́lẹ̀ rí tí ń jẹ àjẹyó.Àgàn ti di ọlọ́mọ meje,ọlọ́mọ pupọ ti di aláìní.