13. Ṣugbọn Saulu dá wọn lóhùn pé, “A kò ní pa ẹnikẹ́ni lónìí, nítorí pé, òní ni ọjọ́ tí OLUWA gba Israẹli là.”
14. Samuẹli wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ sí Giligali, kí á lè túbọ̀ fi ìdí ìjọba Saulu múlẹ̀.”
15. Gbogbo wọn bá pada lọ sí Giligali, wọ́n sì fi Saulu jọba níwájú OLUWA. Wọ́n rú ẹbọ alaafia, Saulu ati àwọn ọmọ Israẹli sì jọ ṣe àjọyọ̀ ńlá.