24. Nígbà tí ó gba ọmú lẹ́nu rẹ̀, ó mú un lọ́wọ́ lọ sí Ṣilo. Nígbà tí ó ń lọ, ó mú akọ mààlúù ọlọ́dún mẹta kan lọ́wọ́, ati ìyẹ̀fun ìwọ̀n efa kan, ati ọtí waini ẹ̀kún ìgò aláwọ kan. Ó sì mú Samuẹli lọ sí Ṣilo ní ilé OLUWA, ọmọde ni Samuẹli nígbà náà.
25. Lẹ́yìn tí wọ́n ti pa akọ mààlúù náà tán, wọ́n mú Samuẹli tọ Eli lọ.
26. Hana bèèrè lọ́wọ́ Eli pé, “Oluwa mi, ǹjẹ́ o ranti mi mọ́? Èmi ni obinrin tí o rí níjelòó, tí mo dúró níhìn-ín níwájú rẹ, tí mò ń gbadura sí OLUWA.
27. Ọmọ yìí ni mò ń tọrọ lọ́wọ́ OLUWA, ó sì fún mi ní ohun tí mo bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀.
28. Nítorí náà, mo wá ya ọmọ náà sọ́tọ̀ fún OLUWA, ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ yóo jẹ́ ti OLUWA.”Lẹ́yìn náà, wọ́n sin OLUWA níbẹ̀.