36. Irú anfaani ńlá báyìí kò tọ́ sí mi láti ọ̀dọ̀ ọba, nítorí náà, n óo bá ọba gun òkè odò Jọdani, n óo sì bá ọ lọ sí iwájú díẹ̀ ni.
37. Lẹ́yìn náà, jọ̀wọ́ jẹ́ kí n pada lọ sí ilé mi, kí n lè kú sí ìlú mi, nítòsí ibojì àwọn òbí mi. Kimhamu ọmọ mi nìyí, jẹ́ kí ó máa bá ọ lọ, kí o sì ṣe ohun tí ó bá tọ́ ní ojú rẹ fún un.”
38. Ọba dáhùn pé, “N óo máa mú Kimhamu lọ, ohunkohun tí ó bá sì bèèrè, ni n óo ṣe fún un.”
39. Lẹ́yìn náà ni Dafidi ati gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ gòkè odò Jọdani. Ó kí Basilai, ó fi ẹnu kò ó ní ẹnu, ó sì súre fún un; Basilai bá pada sí ilé rẹ̀.
40. Lẹ́yìn tí àwọn ará ilẹ̀ Juda, ati ìdajì àwọn ọmọ Israẹli ti sin ọba kọjá odò, ọba lọ sí Giligali, Kimhamu sì bá a lọ.
41. Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá wá sọ́dọ̀ ọba, wọ́n sì bi í pé, “Kabiyesi, kí ló dé tí àwọn eniyan Juda, àwọn arakunrin wa, fi lérò pé àwọn ní ẹ̀tọ́ láti mú ọ lọ, ati láti sin ìwọ ati ìdílé rẹ, ati àwọn eniyan rẹ kọjá odò Jọdani?”