1. Joabu, ọmọ Seruaya, ṣe akiyesi pé ọkàn Absalomu ń fa Dafidi pupọ.
2. Nítorí náà, ó ranṣẹ sí ọlọ́gbọ́n obinrin kan, tí ń gbé Tekoa. Nígbà tí obinrin yìí dé, Joabu wí fún un pé, “Ṣe bí ẹni pé o wà ninu ọ̀fọ̀, wọ aṣọ ọ̀fọ̀, má fi òróró para, kí o sì fi irun rẹ sílẹ̀ játijàti. Ṣe bí ẹni tí ó ti wà ninu ọ̀fọ̀ fún ọjọ́ pípẹ́;
3. kí o lọ sọ́dọ̀ ọba, kí o sì sọ ohun tí n óo sọ fún ọ yìí fún un.” Joabu bá kọ́ ọ ní ohun tí yóo wí.
4. Obinrin ará Tekoa náà bá tọ ọba lọ, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó dojúbolẹ̀, ó sì kí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ó wí fún un báyìí pé, “Kabiyesi, gbà mí.”
5. Ọba bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni o fẹ́?”Ó dá ọba lóhùn pé, “Kabiyesi, opó ni mí, ọkọ mi ti kú.
6. Ọmọkunrin meji ni mo bí. Ní ọjọ́ kan, àwọn mejeeji ń bá ara wọn jà ninu pápá, kò sì sí ẹnikẹ́ni nítòsí láti là wọ́n, ni ọ̀kan ninu wọn bá lu ekeji rẹ̀ pa.